Wọ́n ti sin òkú Họnọrébù tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Àríwá Ìbàdàn nílé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin l’Àbújá, Ọlájídé Akínrẹ̀mí tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí “Jagaban” ní ilé rẹ̀ tó wà ní Temidire Estate ní agbègbè Ológúnẹrú nílùú Ìbàdàn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí, ará, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti àwọn olóṣèlú ni wọ́n kóra jọpọ̀ láti ṣe ìdárò olóògbé náà.
Lára àwọn olóṣèlú tó péjú pésẹ̀ sí ibi ètò ìsìnkú náà ni olùdíje tẹlẹ rí sí ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sẹ́nítọ̀ Tẹslim Fọlarin, aṣojú ilé ìgbìmò aṣojú-ṣòfin tẹlẹ rí, Shina Peller, aṣojú ilé ìgbìmò aṣojú-ṣòfin, Họnọrebu Stanley Adedeji Odidiọmọ, aṣojú ilé ìgbìmò aṣoju-ṣofin tẹlẹ rí, Saheed Fìjàbí ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ níbi ètò ìsìnkú náà, ní ibi tó ti ṣe àlàyé pe títí láé ni òun yóò máa ṣe àfẹ́rí olóògbé Akinrẹmi nítorí èèyàn dáadáa tó sì jẹ́ ọkọ rere ni.
Aṣojú ilé ìgbìmò aṣòfın tẹ́lẹ̀ rí, Shina Peller ṣe àlàyé pé ariwo olóṣèlú tó di olóògbé ní aráyé ń pá, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní òun pàdánù.
Peller fí kún ọrọ̀ rẹ̀ pé láàárín ọjọ́ méjì sí àsìkò tí Olajide Akinremi jáde láyé ni àwọn jọ ń sọ̀rọ̀ léraléra.
Ó sọ pé kódà, àwọn ṣí jọ sọ̀rọ̀ láàárọ̀ ọjọ́ tí ó jáde láyé.
Láti ẹnu ìloro àdúgbò olóògbé náà títí dé inú ilé rẹ̀ tí wọn sin ín sí ni ẹsẹ̀ kò ti gbà èrò. Ariwo oró, ẹkùn àti àbámọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó wá kẹdun fi dìrọ mọ́ ọkọ̀ tó gbé òkú náà wá sílé.




